Tiwa Savage, Ọba Orin Afrobeats, ńbá ètò ìtanijẹ tí a fí ńmú obìrin sìn wọ ìyá ìjà

0

Ní ìgbà tí à ńṣe ìfòròwánilénuwò yìí, Savage sọ fún mi pẹ̀lú ìgboyà wípé àwọn kò tíì fí ìyẹ̀fun-àtẹ́lẹ̀ kan ojú àwọn fún ọdún méjì gbáko. Yálà wọ́n wà n’ìlé, wọ́n jáde tàbí fún yíya àwòrán— bẹ́ẹ̀ni pẹlú àwòrán tí wọ́n yà fún ojú ewé kínní Allure— wọn kò lòó píìn. Ǹjẹ́ lára ìfiraẹni hàn, gbà mí bí mo ṣe rí, wọn ni ípinnu yìí? Bẹ́ẹ̀ni, bẹ́ẹ̀ dẹ̀ tún kọ́: “Mo pàdé Naomi ní bíi ọdún mẹ́ta sẹ́hìn, nínú ọ̀rọ rẹ̀ o wípé ọ̀kan nínú àwọn oun tí kò lò mọ́ ni ìyẹ̀fun-àtẹ́lẹ̀, ọ̀rọ̀ ọ̀hún kò kọ́kọ́ yé mi, ‘bíi báwòo?’ Èmi náà wá pinnu láti má lo ìyẹ̀fun-àtẹ́lẹ̀ mọ́.” Ní tòótọ: Ìgbà kígbà tí Naomi ọmọ Campbell bá fún ní n’ìmọràn pàápàá lórí oun àmúṣoge, gbogbo ènìyàn ló yẹ kó gbàá. Ṣùgbọ́n fún Savage oun ti ó wùún ní àti dá wàhálà ọ̀hún kọjá. Yíyọ ìyẹ̀fun-àtẹ́lẹ̀ kúrò nínú hílàhílo ìṣètò wọ́n tó ti kún fọ́nfọ́n tẹ́lẹ̀, bẹ́ẹ̀ kò yọ kúrò lára ẹwà wọn. Ìṣe ara ẹní lóge, bíi ìrìn àjò ayé wọn nísìsiyìí, gbọ́dọ̀ jẹ́ ìtura. Wọ́n sọ wípé, “Tí mbá ti rì Ìyẹ̀fun, blush, tìróò, àti ìkùntè, ó parí.”

Savage jẹ́ olóòótọ, ọmọnìyàn, àti ní ìgbà míràn, yíó ma ṣe bíi ọmọ ilè-íwè(ní ṣe ni wọ́n fi’ra wọn ṣe yẹ̀yẹ́ nípa ìfẹ wọn sì Lee Min-Ho, ìràwọ̀ òṣèré nlá ni Korea. Wọ́n ńsọ fún ọmọ wọn wípé “Bàbá ẹ tuntun ló ńwò yẹn.” Bí wọ́n ṣe ńwo Legend of the Blue Sea). Ohun tí wọ́n fi ọjọ́ wọn ṣe ko ju kí wọ́n ka bíbélì, kí wọ́n wo Netflix, kí wọ́n ṣe àṣàrò fún ra wọn, àti kí wọ́n má lọ sí orí àwùjọ-ayélújárá(wọ́n ní ẹnití ó ńbá wọ́n ṣé).

Wọ́n tún ńro bí wọ́n ṣé ma fi ọ̀rọ̀ tó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ làákàyè sí inú orin wọn. Nínú ìpele tuntun ayé wọn yìí, Savage fẹ mú àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ wọ ìrìn-àjò tí kò ní ‘orin ìfẹ, àwọn orin tí ó dùn, tí a lè rẹ́rìín músẹ́ sí’. L’ẹ́yín ọdún kan gbáko ti àwọn ọlọ́pàá tú ìbẹ̀rú b’ojo bá àwọn ará ìlú, tí ará-ìlú sì kọjú sí wọn pẹlú #EndSARS, àti ìpànìyàn tí óò ṣẹlẹ̀ ní Lekki Tollgate tí kò jìnà sí ilé rẹ̀, Savage tí dojú kọ àwọn oun tí ó ṣe pàtàkì. Gbogbo ọdún tó kọjá ló fí wo ìròyìn àgbáyé tí ó sì bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn ọ̀rọ̀ tó kù díẹ̀ káátó ní ilẹ̀ẹ Nigeria, àwọn nkán bíi ìfipá bá ni l’òpọ̀ tí ó ńṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọdé’bìrin. Pẹ̀lú ìrètí wípé léhìn tí họ́ùhọ̀ù bá tán ní àwùjọ-ayélujára, ipá láti dá ààbò bo àwọn aláìní agbára kò ní tán. Ó’ dá Ilé iṣẹ́ ọpọlọ We are tired, sílẹ̀ láti ṣe ìrànlọ́wọ́ òfin àti ìdáàbòbò fún àwọn tí orí yọ lẹyìn ìfipá báni lòpọ̀. Àímọye ìgbà ní àwọn olóṣèlú àti olórí ẹ̀sìn bínú sí orin Savage tí ó ńbá jẹgúdú-jẹrá wí. Ṣùgbọ́n fún Savage: “Kìí kúkú ṣe wípé mó ńwá kí orin mí gbanájẹ, tàbí kó pariwo ní’lé ijó, tàbí kí ọ̀gọ̀lọgọ̀ ènìyàn fetí sí orin mi,” wọ́n sọ̀rọ̀ síwájú wípé, “Ó dájú wípé gbogbo àgbáyé ní nkán bá lọ́wọ́lọ́wọ́ mo sì fẹ́ ṣe ìwọnba tí mo le ṣe láti mú dára.”

Ìwé Ìṣoge Lagos láti ọwọ́ Tiwa Savage.

Ìràwọ̀ àgbáyé Afrobeats fún wa ni ọ̀rọ̀ kínkín to gbankọgbì— ǹjẹ̀ o ti lo ọṣẹ dúdú láti Africa rí?— àkàpé ohùn àmúṣẹwà tiwantiwa tó fẹràn.

FOLLOW US ON GOOGLE NEWS

Source

Leave a comment